Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:28-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Iwọ ti ba awọn ara Assiria ṣe panṣaga pẹlu, nitori iwọ kò ni itẹlọrun; nitotọ, iwọ ti ba wọn ṣe panṣaga, sibẹsibẹ kò si le tẹ́ ọ lọrùn,

29. Iwọ si ti sọ agbere rẹ di pupọ lati ilẹ Kenaani de Kaldea; sibẹsibẹ eyi kò si tẹ́ ọ lọrun nihinyi.

30. Oluwa Ọlọrun wipe, aiyà rẹ ti ṣe alailera to, ti iwọ nṣe nkan wọnyi, iṣe agídi panṣaga obinrin;

31. Nitipe iwọ kọ́ ile giga rẹ ni gbogbo ikoríta, ti o si ṣe ibi giga rẹ ni gbogbo ita; iwọ kò si wa dabi panṣaga obinrin, nitipe iwọ gan ọ̀ya.

32. Ṣugbọn gẹgẹ bi aya ti o ṣe panṣaga, ti o gbà alejo dipo ọkọ rẹ̀!

33. Nwọn nfi ẹbùn fun gbogbo awọn panṣaga, ṣugbọn iwọ fi ẹbùn rẹ fun gbogbo awọn olufẹ rẹ, iwọ si ta wọn lọrẹ, ki nwọn le tọ̀ ọ wá ni ihà gbogbo fun panṣaga rẹ.

34. Eyiti o yatọ si ti awọn obinrin miran si mbẹ ninu rẹ, ninu panṣaga rẹ, ti ẹnikan kò tẹ̀le ọ lati ṣe panṣaga: ati nitipe iwọ ntọrẹ, ti a kò si tọrẹ fun ọ nitorina iwọ yatọ.

35. Nitorina, iwọ panṣaga, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:

36. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti a dà ẹgbin rẹ jade, ti a si ri ihoho rẹ nipa panṣaga rẹ pẹlu awọn olufẹ rẹ, ati pẹlu gbogbo oriṣa irira rẹ, ati nipa ẹjẹ awọn ọmọ rẹ, ti iwọ fi fun wọn:

37. Si kiye si i, Emi o kó gbogbo awọn olufẹ rẹ jọ, awọn ẹniti iwọ ti ba jaiye, ati gbogbo awọn ti iwọ ti fẹ, pẹlu gbogbo awọn ti iwọ ti korira; ani emi o gbá wọn jọ kakiri si ọ, emi o si fi ihoho rẹ hàn wọn, ki nwọn ki o le ri gbogbo ihoho rẹ.

38. Emi o si dá ọ lẹjọ, gẹgẹ bi a ti da awọn obinrin lẹjọ ti o ba igbeyawo jẹ ti nwọn si ta ẹjẹ silẹ; emi o si fi ẹjẹ fun ọ, ni irúnu ati ni ijowu.

39. Emi o si fi ọ le wọn lọwọ pẹlu, nwọn o si wo ibi giga rẹ, nwọn o si wo ibi giga rẹ palẹ: nwọn o si bọ aṣọ rẹ pẹlu, nwọn o si gbà ohun ọṣọ rẹ didara, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho, ati ni goloto.

40. Nwọn o mu ẹgbẹ́ kan wá si ọ pẹlu, nwọn o si sọ ọ li okuta, nwọn o si fi idà wọn gún ọ yọ.

41. Nwọn o si fi iná kun gbogbo ile rẹ; nwọn o si mu idajọ ṣẹ si ọ lara niwaju obinrin pupọ; emi o si jẹ ki o fi panṣaga rẹ mọ, iwọ pẹlu kì yio si funni ni ọ̀ya mọ.

42. Bẹ̃ni emi o jẹ ki irúnu mi si ọ ki o dá, owú mi yio si kuro lọdọ rẹ, emi o si dakẹjẹ, emi kì yio binu mọ.

43. Nitoripe iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, ṣugbọn o si mu mi kanra ninu gbogbo nkan wọnyi; si kiye si i, nitorina emi pẹlu o san ẹsan ọ̀na rẹ si ọ lori, ni Oluwa Ọlọrun wi: iwọ kì yio si ṣe ifẹkufẹ yi lori gbogbo ohun irira rẹ mọ.

44. Kiyesi i, olukuluku ẹniti npowe ni yio powe yi si ọ, wipe, Bi iyá ti ri, bẹ̃ni ọmọ rẹ̀ obinrin.

45. Iwọ ni ọmọ iyá rẹ ti o kọ̀ ọkọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀; iwọ ni arabinrin awọn arabinrin rẹ, ti o kọ̀ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn: ará Hiti ni iyá rẹ, ará Amori si ni baba rẹ.

46. Ẹgbọn rẹ obinrin si ni Samaria, on ati awọn ọmọbinrin rẹ ti ngbe ọwọ́ osì rẹ: ati aburo rẹ obinrin ti ngbe ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.

Ka pipe ipin Esek 16