Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 11:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Oluwa Ọlọrun wipe, Ẹnyin ti bẹ̀ru idà, emi o si mu idà wa sori nyin.

9. Emi o si mu nyin kuro lãrin rẹ̀, emi o si fi nyin le awọn alejo lọwọ, emi o si mu idajọ ṣẹ si nyin lara.

10. Nipa idà li ẹnyin o ṣubu; emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

11. Ilu yi ki yio ṣe ìgba fun nyin, bẹ̃ni ẹnyin kì yio jẹ ẹran lãrin rẹ̀; ṣugbọn emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli.

12. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitoriti ẹnyin kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni ẹnyin kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn ẹnyin ti hu ìwa awọn keferi ti o wà yi nyin ka.

13. O si ṣe, nigbati mo sọtẹlẹ, Pelatia ọmọ Benaiah kú. Mo si dojubolẹ, mo si fi ohùn rara kigbe, mo si wipe, A! Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha ṣe aṣetan iyokù Israeli bi?

14. Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

15. Ọmọ enia, awọn ará rẹ, ani awọn ará rẹ, awọn ọkunrin ninu ibatan rẹ, ati gbogbo ile Israeli patapata, ni awọn ti awọn ara Jerusalemu ti wi fun pe, Ẹ jina si Oluwa; awa ni a fi ilẹ yi fun ni ini.

16. Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Bi mo tilẹ ti tá wọn nù réré lãrin awọn keferi; bi mo si ti tú wọn ka lãrin ilẹ pupọ, sibẹ emi o jẹ ibi mimọ́ kekere fun wọn ni ilẹ ti wọn o de.

17. Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Emi tilẹ kó nyin kuro lọdọ awọn orilẹ-ède; emi o si kó nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ká si, emi o si fun nyin ni ilẹ Israeli.

18. Nwọn o si wá sibẹ, nwọn o si mu gbogbo ohun irira rẹ̀ ati gbogbo ohun ẽri rẹ̀ kuro nibẹ.

19. Emi o si fun wọn li ọkàn kan, emi o si fi ẹmi titun sinu nyin; emi o si mu ọkàn okuta kuro lara wọn, emi o si fun wọn li ọkàn ẹran:

Ka pipe ipin Esek 11