Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 11:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitorina sọtẹlẹ si wọn, Ọmọ enia, sọtẹlẹ.

5. Ẹmi Oluwa si bà le mi, o si wi fun mi pe, Sọ̀rọ; Bayi li Oluwa wi; Bayi li ẹnyin ti wi, Ile Israeli, nitoriti mo mọ̀ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin.

6. Ẹnyin ti sọ okú nyin di pupọ̀ ni ilu yi, ẹnyin si ti fi okú kún igboro rẹ̀,

7. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Awọn okú nyin ti ẹnyin ti tẹ́ si ãrin rẹ̀, awọn ni ẹran, ilu yi si ni ìgba; ṣugbọn emi o mu nyin jade kuro lãrin rẹ̀.

8. Oluwa Ọlọrun wipe, Ẹnyin ti bẹ̀ru idà, emi o si mu idà wa sori nyin.

9. Emi o si mu nyin kuro lãrin rẹ̀, emi o si fi nyin le awọn alejo lọwọ, emi o si mu idajọ ṣẹ si nyin lara.

10. Nipa idà li ẹnyin o ṣubu; emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

11. Ilu yi ki yio ṣe ìgba fun nyin, bẹ̃ni ẹnyin kì yio jẹ ẹran lãrin rẹ̀; ṣugbọn emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli.

12. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitoriti ẹnyin kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni ẹnyin kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn ẹnyin ti hu ìwa awọn keferi ti o wà yi nyin ka.

13. O si ṣe, nigbati mo sọtẹlẹ, Pelatia ọmọ Benaiah kú. Mo si dojubolẹ, mo si fi ohùn rara kigbe, mo si wipe, A! Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha ṣe aṣetan iyokù Israeli bi?

14. Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

Ka pipe ipin Esek 11