Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 8:15-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ṣugbọn nigbati Farao ri pe isimi wà, o mu àiya rẹ̀ le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

16. OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti.

17. Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti.

18. Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran.

19. Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

20. OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.

21. Bi iwọ kò ba si jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, emi o rán ọwọ́ eṣinṣin si ọ, ati sara iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu awọn ile rẹ: gbogbo ile awọn ara Egipti ni yio si kún fun ọwọ́ eṣinṣin, ati ilẹ ti nwọn gbé wà pẹlu.

22. Li ọjọ́ na li emi o yà ilẹ Goṣeni sọ̀tọ, ninu eyiti awọn enia mi tẹ̀dó si, ti eṣinṣin ki yio sí nibẹ̀; nitori ki iwọ ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA lãrin ilẹ aiye.

23. Emi o si pàla si agbedemeji awọn enia mi ati awọn enia rẹ: li ọla ni iṣẹ-amì yi yio si wà.

24. OLUWA si ṣe bẹ̃; ọwọ́ eṣinṣin ọ̀pọlọpọ si dé sinu ile Farao, ati sinu ile awọn iranṣẹ rẹ̀: ati ni gbogbo ilẹ Egipti, ilẹ na bàjẹ́ nitori ọwọ́ eṣinṣin wọnni.

25. Farao si ranṣẹ pè Mose ati Aaroni o si wipe; Ẹ ma lọ ṣẹbọ si Ọlọrun nyin ni ilẹ yi.

26. Mose si wipe, Kò tọ́ lati ṣe bẹ̃; nitori awa o fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ si OLUWA Ọlọrun wa: wò o, awa le fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ li oju wọn, nwọn ki yio ha sọ wa li okuta?

27. Awa o lọ ni ìrin ijọ́ mẹta sinu ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa, bi on o ti paṣẹ fun wa.

28. Farao si wipe, Emi o jẹ ki ẹnyin lọ, ki ẹ le rubọ si OLUWA Ọlọrun nyin ni ijù; kìki ki ẹnyin ki o máṣe lọ jìna jù: ẹ bẹ̀bẹ fun mi.

29. Mose si wipe, Kiyesi i, emi njade lọ kuro lọdọ rẹ, emi o si bẹ̀ OLUWA ki ọwọ́ eṣinṣin wọnyi ki o le ṣi kuro lọdọ Farao, kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀, li ọla: kìki ki Farao ki o máṣe ẹ̀tan mọ́ li aijẹ ki awọn enia na ki o lọ rubọ si OLUWA.

30. Mose si jade kuro lọdọ Farao, o si bẹ̀ OLUWA.

31. OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; o si ṣi ọwọ́ eṣinṣin na kuro lọdọ Farao, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀; ọkan kò kù.

32. Farao si mu àiya rẹ̀ le nigbayi pẹlu, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.

Ka pipe ipin Eks 8