Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 35:21-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nwọn si wá, olukuluku ẹniti ọkàn rẹ́ ru ninu rẹ̀, ati olukuluku ẹniti ọkàn rẹ̀ mu u fẹ́, nwọn si mú ọrẹ OLUWA wá fun iṣẹ agọ́ ajọ na, ati fun ìsin rẹ̀ gbogbo, ati fun aṣọ mimọ́ wọnni.

22. Nwọn si wá, ati ọkunrin ati obinrin, iye awọn ti ọkàn wọn fẹ́, nwọn si mú jufù wá, ati oruka-eti, ati oruka-àmi, ati ilẹkẹ wurà, ati onirũru ohun ọṣọ́ wurà; ati olukuluku enia ti o nta ọrẹ, o ta ọrẹ wurà fun OLUWA.

23. Ati olukuluku enia lọdọ ẹniti a ri aṣọ-alaró, ati elesè àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ daradara, ati irun ewurẹ, ati awọ àgbo pupa, ati awọ seali, mú wọn wá.

24. Olukuluku ẹniti o ta ọrẹ fadakà ati idẹ, o mú ọrẹ OLUWA wá: ati olukuluku enia lati ọdọ ẹniti a ri igi ṣittimu fun iṣẹkiṣẹ ìsin na, mú u wá.

25. Ati gbogbo awọn obinrin ti iṣe ọlọgbọ́n inu, nwọn fi ọwọ́ wọn ranwu, nwọn si mú eyiti nwọn ran wá, ti alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ daradara.

26. Ati gbogbo awọn obinrin inu ẹniti o ru soke li ọgbọ́n nwọn ran irun ewurẹ.

27. Ati awọn ijoye mú okuta oniki wá, ati okuta ti a o tò, fun ẹ̀wu-efodi nì, ati fun igbàiya nì;

28. Ati olõrùn, ati oróro; fun fitila, ati fun oróro itasori, ati fun turari didùn.

29. Awọn ọmọ Israeli ta ọrẹ atinuwa fun OLUWA; olukuluku ọkunrin ati obinrin, ẹniti ọkàn wọn mu wọn fẹ́ lati mú u wá fun onirũru iṣẹ, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe lati ọwọ́ Mose wá,

30. Mose si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Wò o, OLUWA ti pè Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, li orukọ.

31. O si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, li oyé, ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà;

32. Ati lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ,

33. Ati li okuta gbigbẹ́ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà.

34. O si fi sinu ọkàn rẹ̀ lati ma kọni, ati on, ati Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani.

35. O si fi ọgbọ́n inu kún wọn, lati ṣe onirũru iṣẹ, ti alagbẹdẹ, ati ti ọnà, ati ti agunnà, li aṣọ-alaró, ati li elesè-àluko, li ododó, ati li ọ̀gbọ daradara, ati ti ahunṣọ, ati ti awọn ẹniti nṣe iṣẹkiṣẹ ati ti awọn ẹniti nhumọ̀ iṣẹ-ọnà.

Ka pipe ipin Eks 35