Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 5:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Mú àwọn àgbà obinrin bí ìyá; mú àwọn ọ̀dọ́ obinrin bí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ pẹlu ìwà mímọ́ ní ọ̀nà gbogbo.

3. Bu ọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ alailẹnikan.

4. Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun.

5. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru.

6. Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé.

7. Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn.

8. Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ.

9. Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan,

10. tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo.

11. Ṣọ́ra nípa kíkọ orúkọ àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ sílẹ̀, nítorí nígbà tí ara wọn bá gbóná, wọn yóo kọ ètò ti Kristi sílẹ̀, wọn yóo fẹ́ tún lọ́kọ.

12. Wọn yóo wá gba ẹ̀bi nítorí wọ́n ti kọ ẹ̀jẹ́ wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀.

13. Ati pé nígbà tí wọn bá ń tọ ojúlé kiri, wọ́n ń kọ́ láti ṣe ìmẹ́lẹ́. Kì í sì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nìkan, wọn a máa di olófòófó ati alátojúbọ̀ ọ̀ràn-ọlọ́ràn, wọn a sì máa sọ ohun tí kò yẹ.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 5