Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 1:15-20 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

16. Ìdí tí ó fi ṣàánú mi nìyí, pé èmi ni Kristi Jesu kọ́kọ́ yọ́nú sí ju ẹnikẹ́ni lọ. Mo wá di àpẹẹrẹ gbogbo àwọn tí wọn yóo gbà á gbọ́ tí wọn yóo sì ní ìyè ainipẹkun.

17. Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin.

18. Timoti ọmọ mi, ọ̀rọ̀ àṣẹ yìí ni mo fi lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wolii sọ nípa rẹ̀ tí mo fi yàn ọ́, pé kí o ja ìjà rere pẹlu agbára àṣẹ yìí.

19. Kí o fi igbagbọ ati ẹ̀rí-ọkàn rere jà. Àwọn nǹkan wọnyi ni àwọn mìíràn kọ̀, tí ọkọ̀ ìgbé-ayé igbagbọ wọn fi rì.

20. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní Himeneu ati Alẹkisanderu, àwọn tí mo ti fà lé Satani lọ́wọ́ kí ó lè bá wọn wí kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù mọ́.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 1