Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 8:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín.

12. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí.

13. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè.

14. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun.

15. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!”

16. Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá.

17. Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu.

18. Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá.

19. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn.

20. Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé:

21. ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun.

22. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún.

Ka pipe ipin Romu 8