Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 3:3-22 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?”

4. Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ,kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.”

5. Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.)

6. Rárá o! Bí Ọlọrun kò bá ní ẹ̀tọ́ láti bínú, báwo ni yóo ṣe wá ṣe ìdájọ́ aráyé?

7. Bí aiṣotitọ mi bá mú kí ògo òtítọ́ Ọlọrun túbọ̀ hàn, kí ni ṣe tí a tún fi ń dá mi lẹ́bi bí ẹlẹ́ṣẹ̀?

8. Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi.

9. Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

10. Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé,“Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan.

11. Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun.

12. Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo wọn kò níláárí mọ́,kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.

13. Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn,ẹ̀tàn kún ẹnu wọn;oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn;

14. ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú.

15. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

16. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn.

17. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia.

18. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.”

19. A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun.

20. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀.

21. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i.

22. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan.

Ka pipe ipin Romu 3