Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 14:7-23 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn.

8. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá.

9. Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè.

10. Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun!

11. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní,‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún,Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ”

12. Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun.

13. Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀.

14. Mo mọ èyí, ó sì dá mi lójú nípa àṣẹ Oluwa Jesu pé kò sí ohunkohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ ní jíjẹ fún ara rẹ̀. Ṣugbọn tí ẹnìkan bá ka nǹkan sí èèwọ̀, èèwọ̀ ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.

15. Nítorí bí o bá mú ìdààmú bá arakunrin rẹ nípa ọ̀ràn oúnjẹ tí ò ń jẹ, a jẹ́ pé, kì í ṣe ìfẹ́ ni ń darí ìgbésí-ayé rẹ mọ́. Má jẹ́ kí oúnjẹ tí ò ń jẹ mú ìparun bá ẹni tí Jesu ti ìtorí rẹ̀ kú.

16. Má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ìsọkúsọ nípa àwọn ohun tí ẹ kà sí nǹkan rere.

17. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni.

18. Ẹni tí ó bá ń sin Kristi báyìí jẹ́ ẹni tí inú Ọlọrun dùn sí, tí àwọn eniyan sì gbà fún.

19. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa lépa àwọn nǹkan tí ń mú alaafia wá, ati àwọn nǹkan tí yóo yọrí sí ìdàgbàsókè láàrin ara wa.

20. Ẹ má ṣe tìtorí oúnjẹ ba iṣẹ́ Ọlọrun jẹ́. A lé sọ pé kò sí oúnjẹ kan tí kò dára, ṣugbọn nǹkan burúkú ni fún ẹni tí ó bá ń jẹ oúnjẹ kan tí ó di nǹkan ìkọsẹ̀ fún ẹlòmíràn.

21. Ó dára bí o kò bá jẹ ẹran, tabi kí o mu ọtí, tabi kí o ṣe ohunkohun tí yóo mú arakunrin rẹ kọsẹ̀.

22. Bí ìwọ bá ní igbagbọ ní tìrẹ, jẹ́ kí igbagbọ tí o ní wà láàrin ìwọ ati Ọlọrun rẹ. Olóríire ni ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò bá dá lẹ́bi lórí nǹkan tí ó bá gbà láti ṣe.

23. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ń ṣiyèméjì bá jẹ kinní kan, ó jẹ̀bi, nítorí tí kò jẹ ẹ́ pẹlu igbagbọ. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkohun tí eniyan kò bá ṣe pẹlu igbagbọ.

Ka pipe ipin Romu 14