7. Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”
8. Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.
9. Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.”
10. Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”
11. Lẹ́yìn náà, Èṣù fi í sílẹ̀. Àwọn angẹli bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún un.
12. Nígbà tí Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ju Johanu sẹ́wọ̀n, ó yẹra lọ sí Galili.
13. Lẹ́yìn tí ó kúrò ní Nasarẹti, ó ń lọ gbè Kapanaumu tí ó wà lẹ́bàá òkun ní agbègbè Sebuluni ati Nafutali.
14. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé:
15. “Ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali,ní ọ̀nà òkun,ní òdìkejì Jọdani,Galili àwọn àjèjì.
16. Àwọn eniyan tí ó jókòó ní òkùnkùnrí ìmọ́lẹ̀ ńlá.Ìmọ́lẹ̀ mọ́ sórí àwọn tí ó jókòóní ilẹ̀ tí òjìji ikú wà.”
17. Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.”
18. Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.