Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 13:7-21 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa.

8. Ṣugbọn àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ń so èso, àwọn mìíràn ń so ọgọọgọrun-un, àwọn mìíràn ọgọọgọta, àwọn mìíràn, ọgbọọgbọn.

9. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń fi òwe bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀?”

11. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a fi àṣírí ìmọ̀ ìjọba ọ̀run hàn, a kò fihan àwọn yòókù wọnyi.

12. Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.

13. Ìdí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nìyí, nítorí wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn.

14. Báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aisaya ṣe ṣẹ sí wọn lára, nígbà tí ó sọ pé.‘Ní ti gbígbọ́, ẹ óo gbọ́,ṣugbọn kò ní ye yín;ní ti pé kí ẹ ríran, ẹ óo wò títí,ṣugbọn ẹ kò ní rí nǹkankan.

15. Ọkàn àwọn eniyan yìí ti le,etí wọn ti di,wọ́n sì ti di ojú wọn.Kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,kí wọn má baà fi etí wọn gbọ́ràn,kí wọn má baà mòye,kí wọn má baà yipada,kí n wá gbà wọ́n là.’

16. “Ṣugbọn ẹ̀yin ṣe oríire tí ojú yín ríran, tí etí yín sì gbọ́ràn.

17. Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn olódodo dàníyàn láti rí àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rí, ṣugbọn wọn kò rí wọn; wọ́n fẹ́ gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́.

18. “Ẹ gbọ́ ìtumọ̀ òwe afunrugbin.

19. Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run, tí nǹkan tí ó gbọ́ kò yé e, tí èṣù wá, tí ó mú ohun tí a gbìn sọ́kàn rẹ̀ lọ: òun ni irúgbìn ti ẹ̀bá ọ̀nà.

20. Irúgbìn ti orí ilẹ̀ olókùúta ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á lẹsẹkẹsẹ.

21. Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà.

Ka pipe ipin Matiu 13