Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 4:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.

2. Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:

3. “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.

4. Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.

5. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀.

6. Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú.

7. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso.

8. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.”

9. Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

10. Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀.

11. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde.

12. Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀ṣugbọn kí wọn má ríran;kí wọn gbọ́ títíṣugbọn kí òye má yé wọn;kí wọn má baà ronupiwada,kí á má baà dáríjì wọ́n.”

13. Ó wá wí fún wọn pé, “Nígbà tí òwe yìí kò ye yín, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ gbogbo àwọn òwe ìyókù?

14. Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀.

15. Àwọn wọnyi ni ti ẹ̀bá ọ̀nà, níbi tí a fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà sí: àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, Satani wá, ó mú ọ̀rọ̀ tí a ti fún sinu ọkàn wọn lọ.

16. Bákan náà ni àwọn ẹlòmíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí òkúta, nígbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọn á fi inú dídùn gbà á.

Ka pipe ipin Maku 4