Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 11:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Wọ́n bá fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí orí rẹ̀, Jesu bá gùn un.

8. Ọpọlọpọ eniyan tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà, àwọn mìíràn tẹ́ ẹ̀ka igi tí wọ́n ya ní pápá.

9. Àwọn tí ó ń lọ ní iwájú ati àwọn tí ó ń bọ̀ ní ẹ̀yìn ń kígbe pé,“Hosana!Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa.

10. Ibukun ni ìjọba tí ń bọ̀,ìjọba Dafidi baba ńlá wa.Hosana ní òkè ọ̀run!”

11. Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

12. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní Bẹtani, ebi ń pa á.

13. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé lókèèrè, ó bá lọ wò ó bí yóo rí èso lórí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ìdí rẹ̀ kò rí ohunkohun àfi ewé, nítorí kò ì tíì tó àkókò èso.

14. Jesu wí fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má rí èso jẹ lórí rẹ mọ́ lae!”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbọ́.

15. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú.

16. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé ohunkohun la àgbàlá Tẹmpili kọjá.

Ka pipe ipin Maku 11