Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.