Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 1:25-40 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.”

26. Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà.

27. Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.”

28. Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili.

29. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu.

30. Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀.

31. Ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó fà á lọ́wọ́ dìde. Ibà náà sì fi í sílẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú oúnjẹ fún wọn.

32. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn wọ̀, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

33. Gbogbo ìlú péjọ sí ẹnu ọ̀nà.

34. Ó ṣe ìwòsàn fún ọpọlọpọ àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àìsàn, ó tún lé ẹ̀mí èṣù jáde. Kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ ẹni tí ó jẹ́.

35. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan.

36. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri.

37. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.”

38. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.”

39. Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

40. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”

Ka pipe ipin Maku 1