Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 7:30-40 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ṣugbọn àwọn Farisi ati àwọn amòfin kọ ìlànà Ọlọrun fún wọn, wọn kò ṣe ìrìbọmi ti Johanu.

31. Jesu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ta ni èmi ìbá fi àwọn eniyan òde òní wé? Ta ni kí a wí pé wọ́n jọ?

32. Wọ́n jọ àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà. Àwọn kan ń pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé, ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, A sun rárà òkú fun yín, ẹ kò sunkún.’

33. Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi dé, kò jẹ, kò mu, ẹ sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’

34. Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu, ẹ ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’

35. Sibẹ a mọ̀ pé ọgbọ́n Ọlọrun tọ̀nà nípa ìṣesí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”

36. Ọ̀kan ninu àwọn Farisi pe Jesu pé kí ó wá bá òun jẹun. Jesu bà lọ sí ilé Farisi yìí lọ jẹun.

37. Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́,

38. ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀.

39. Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

40. Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.”Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.”

Ka pipe ipin Luku 7