Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 7:22-29 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ ohun tí ẹ rí ati ohun tí ẹ gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran; àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́; àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde; à ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

23. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”

24. Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ Johanu lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ nípa Johanu fún àwọn eniyan. Ó ní, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Igi légbélégbé tí afẹ́fẹ́ ń tì sọ́tùn-ún, ati sósì ni bí?

25. Kí ni ẹ jáde lọ wò? Ọkunrin tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye ni bí? Bí ẹ bá fẹ́ rí àwọn tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba.

26. Àní, kí ni ẹ lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ!

27. Òun ni a kọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ, òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’

28. Mo sọ fun yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni jákèjádò ayé yìí tí ó ṣe pataki ju Johanu lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jùlọ ninu ìjọba ọ̀run ṣe pataki jù ú lọ.”

29. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan gbọ́, tí ó fi mọ́ àwọn agbowó-odè pàápàá, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun, wọ́n lọ ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ètò ìrìbọmi Johanu.

Ka pipe ipin Luku 7