Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 7:12-23 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà.

13. Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.”

14. Ni ó bá lọ, ó fi ọwọ́ kan pósí. Àwọn tí wọ́n gbé pósí bá dúró. Ó bá sọ pé, “Ọdọmọkunrin, mo sọ fún ọ, dìde.”

15. Ọdọmọkunrin tí ó ti kú yìí bá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Jesu bà fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.

16. Ẹ̀rù ba gbogbo eniyan, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun, wọ́n ní, “Wolii ńlá ti dìde ni ààrin wa. Ọlọrun ti bojúwo àwọn eniyan rẹ̀.”

17. Ìròyìn ohun tí ó ṣe yìí tàn ká gbogbo Judia ati gbogbo agbègbè ibẹ̀.

18. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ròyìn gbogbo nǹkan wọnyi fún un. Johanu bá pe meji ninu wọn,

19. ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”

20. Nígbà tí àwọn ọkunrin náà dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ní, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó rán wa sí ọ láti bi ọ́ pé, ‘Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?’ ”

21. Ní àkókò náà, Jesu ń wo ọpọlọpọ eniyan sàn ninu àìsàn ati àrùn. Ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọpọlọpọ àwọn afọ́jú ni ó jẹ́ kí wọ́n ríran.

22. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ ohun tí ẹ rí ati ohun tí ẹ gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran; àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́; àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde; à ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

23. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”

Ka pipe ipin Luku 7