Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 4:21-35 BIBELI MIMỌ (BM)

21. ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.”

22. Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”

23. Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ”

24. Ó tún fi kún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí wolii kan tíí ní iyì ní ìlú baba rẹ̀.

25. “Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo.

26. A kò rán Elija sí ọ̀kankan ninu wọn. Ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán an sí ni opó kan ní Sarefati ní agbègbè Sidoni.

27. Àwọn adẹ́tẹ̀ pọ̀ ní Israẹli ní àkókò wolii Eliṣa. Kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a wòsàn, àfi Naamani ará Siria.”

28. Nígbà tí àwọn tí ó wà ninu ilé ìpàdé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí gbogbo wọn.

29. Wọ́n dìde, wọ́n tì í sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibi tí ìlú wọn wà, wọ́n fẹ́ taari rẹ̀ ní ogedengbe.

30. Ṣugbọn ó la ààrin wọn kọjá, ó bá tirẹ̀ lọ.

31. Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi.

32. Ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí pẹlu àṣẹ ni ó fi ń sọ̀rọ̀.

33. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò,

34. ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.”

35. Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára.

Ka pipe ipin Luku 4