Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 22:25-42 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn.

26. Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ.

27. Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ.

28. “Ẹ̀yin ni ẹ dúró tì mí ní gbogbo àkókò ìdánwò mi.

29. Gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti fi ìjọba fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà fi ìjọba fun yín,

30. kí ẹ lè bá mi jẹ, kí ẹ sì bá mi mu ninu ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli mejila.

31. “Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà.

32. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.”

33. Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.”

34. Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”

35. Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?”Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!”

36. Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan.

37. Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.”

38. Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.”Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!”

39. Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e.

40. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”

41. Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura.

42. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [

Ka pipe ipin Luku 22