Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 18:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Àwọn eniyan ń gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá, pé kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tí wọ́n gbé wọn wá wí.

16. Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.

17. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.”

18. Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

19. Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo.

20. Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ”

21. Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.”

22. Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23. Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bàjẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.

24. Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun.

25. Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun.”

26. Àwọn tí ó gbọ́ ní, “Ta wá ni a óo gbà là?”

27. Ó dáhùn pé, “Ohun tí kò ṣeéṣe fún eniyan, ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Luku 18