Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 18:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Èyí Farisi dá dúró, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, ‘Ọlọrun, mo dúpẹ́ pé ń kò dàbí àwọn yòókù, àwọn oníwọ̀ra, alaiṣootọ, alágbèrè. N kò tilẹ̀ dàbí agbowó-odè yìí.

12. Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’

13. “Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’

14. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”

15. Àwọn eniyan ń gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá, pé kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tí wọ́n gbé wọn wá wí.

16. Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.

17. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.”

18. Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

19. Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo.

20. Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ”

21. Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.”

Ka pipe ipin Luku 18