Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 16:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. “Ọkunrin kán wà tí ó lówó. Aṣọ àlàárì ati àwọn aṣọ olówó iyebíye mìíràn ni ó máa ń wọ̀. Oúnjẹ àdídùn ni ó máa ń jẹ, lojoojumọ ni ó máa ń se àsè.

20. Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò.

21. Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀.

22. “Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín.

23. Ní ipò òkú ni ó rí ara rẹ̀, tí ó ń joró. Ó wá rí Abrahamu ní òkèèrè pẹlu Lasaru ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

24. Ó bá pè é, ó ní, ‘Abrahamu, Baba, ṣàánú mi. Rán Lasaru kí ó ti ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó wá kán an sí mi láhọ́n, nítorí mò ń jẹ ìrora ninu iná yìí.’

25. “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ, ranti pé nígbà tí o wà láyé, kìkì ohun rere ni o gbà, nígbà tí ó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni Lasaru gbà. Nisinsinyii, ìdẹ̀ra ti dé bá Lasaru nígbà tí ìwọ ń jẹ̀rora.

26. Ati pé ọ̀gbun ńlá kan wà láàrin àwa ati ẹ̀yin, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó bá fẹ́ kọjá sí ọ̀dọ̀ yín kò ní lè kọjá; bákan náà àwọn tí ó bá fẹ́ ti ọ̀hún kọjá wá sí ọ̀dọ̀ wa kò ní lè kọjá.’

27. Olówó náà wá sọ pé, ‘Baba, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, rán Lasaru lọ sí ilé baba mi.

28. Arakunrin marun-un ni mo ní; kí ó lọ kìlọ̀ fún wọn kí àwọn náà má baà wá sí ibi oró yìí.’

Ka pipe ipin Luku 16