Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 12:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀.

3. Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀.

4. “Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀!

5. N óo fi ẹni tí ẹ̀ bá bẹ̀rù hàn yín. Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá pa ara tán, ó ní àṣẹ láti tún sọ eniyan sinu ọ̀run àpáàdì. Mo sọ fun yín, ẹ bẹ̀rù olúwarẹ̀.

6. “Mo ṣebí kọbọ meji ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ marun-un. Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí Ọlọrun fi ojú fò dá.

7. Àní sẹ́, gbogbo irun orí yín ni ó níye. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.

8. “Mo sọ fun yín, gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun.

9. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan ni a óo sẹ́ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun.

10. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ-Eniyan, a óo dáríjì í. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò ní dáríjì í.

11. “Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ.

12. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóo kọ yín ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ ní àkókò náà.”

Ka pipe ipin Luku 12