orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 13 BIBELI MIMỌ (BM)

Ìkìlọ̀ Ìgbẹ̀yìn

1. Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.

2. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún àwọn tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ ati àwọn yòókù, tí mo tún sọ nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín lẹẹkeji, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń sọ nisinsinyii tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá tún dé, n kò ní ṣojú àánú;

3. nígbà tí ó ti jẹ́ pé ẹ̀rí ni ẹ̀ ń wá pé Kristi ń lò mí láti sọ̀rọ̀. Kristi kì í ṣe aláìlera ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu yín.

4. Òtítọ́ ni pé a kàn án mọ́ agbelebu ní àìlera, ṣugbọn ó wà láàyè nípa agbára Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé àwa náà jẹ́ aláìlera pẹlu rẹ̀, ṣugbọn a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀ nípa agbára Ọlọrun ninu ìbálò wa pẹlu yín.

5. Ẹ yẹ ara yín wò bí ẹ bá ń gbé ìgbé-ayé ti igbagbọ. Ẹ yẹ ara yín wò. Àbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀ pé Kristi Jesu wà ninu yín? Àfi bí ẹ bá ti kùnà nígbà tí ẹ yẹ ara yín wò!

6. Ṣugbọn mo ní ìrètí pé ẹ mọ̀ pé ní tiwa, àwa kò kùnà.

7. À ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ẹ má ṣe nǹkan burúkú kan, kì í ṣe pé nítorí kí á lè farahàn bí ẹni tí kò kùnà, ṣugbọn kí ẹ̀yin lè máa ṣe rere, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa dàbí ẹni tí ó kùnà.

8. Nítorí a kò lè ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí òtítọ́, àfi òtítọ́.

9. Nítorí náà inú wa dùn nígbà tí àwa bá jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára. Èyí ni à ń gbadura fún, pé kí ẹ tún ìgbé-ayé yín ṣe.

10. Ìdí tí mo fi ń kọ gbogbo nǹkan wọnyi nígbà tí n kò sí lọ́dọ̀ yín ni pé nígbà tí mo bá dé, kí n má baà fi ìkanra lo àṣẹ tí Oluwa ti fi fún mi láti fi mú ìdàgbà wá, kì í ṣe láti fi wo yín lulẹ̀.

Gbolohun Ìdágbére

11. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín.

12. Ẹ fi ìfẹnukonu ti alaafia kí ara yín. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín.

13. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi, ati ìfẹ́ Ọlọrun ati ìdàpọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu gbogbo yín.