Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 22:25-30 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Bí wọ́n ti ń dè é mọ́lẹ̀ láti máa nà án, Paulu bi balogun ọ̀rún tí ó dúró pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti na ọmọ-ìbílẹ̀ Romu láì tíì dá a lẹ́jọ́?”

26. Nígbà tí balogun ọ̀rún gbọ́, ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó bi í pé, “Kí lẹ fẹ́ ṣe? Ọmọ ìbílẹ̀ Romu ni ọkunrin yìí o!”

27. Ní ọ̀gágun bá lọ bi Paulu, ó ní, “Wí kí n gbọ́, ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni ọ́?”Paulu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

28. Ọ̀gágun náà bá dá a lóhùn pé, “Ọpọlọpọ owó ni mo ná kí n tó di ọmọ-ìbílẹ̀ Romu.”Ṣugbọn Paulu ní, “Ní tèmi o, wọ́n bí mi bẹ́ẹ̀ ni.”

29. Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ bá bìlà. Ẹ̀rù wá ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni Paulu, àtipé òun ti fi ẹ̀wọ̀n dè é.

30. Lọ́jọ́ keji, ọ̀gágun náà tú Paulu sílẹ̀. Ó fẹ́ mọ òtítọ́ ẹ̀sùn tí àwọn Juu mú wá nípa rẹ̀. Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ. Ó bá mú Paulu lọ siwaju wọn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 22