Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 21:29-40 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Wọ́n sọ báyìí nítorí pé wọ́n ti kọ́kọ́ rí Tirofimọsi ará Efesu pẹlu Paulu láàrin ìlú, wọ́n wá ṣebí Paulu mú un wọ inú Tẹmpili ni.

30. Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn.

31. Wọ́n fẹ́ pa á ni ìròyìn bá kan ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú.

32. Lójú kan náà ó bá mú àwọn ọmọ-ogun pẹlu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sáré lọ bá wọn. Nígbà tí àwọn èrò rí ọ̀gágun ati àwọn ọmọ-ogun, wọ́n dáwọ́ dúró, wọn kò lu Paulu mọ́.

33. Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe.

34. Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun.

35. Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko.

36. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!”

37. Bí wọ́n ti fẹ́ mú Paulu wọ inú àgọ́ ọmọ-ogun, ó sọ fún ọ̀gágun pé, “Ṣé kò léèwọ̀ bí mo bá bá ọ sọ nǹkankan?”Ọ̀gágun wá bi í léèrè pé, “O gbọ́ èdè Giriki?

38. Ìyẹn ni pé kì í ṣe ìwọ ni ará Ijipti tí ó dá rúkèrúdò sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, tí ó kó ẹgbaaji (4000) àwọn agúnbẹ lẹ́yìn lọ sí aṣálẹ̀?”

39. Paulu dáhùn ó ní, “Juu ni mí, ará Tasu ní ilẹ̀ Silisia. Ọmọ ìlú tí ó lókìkí ni mí. Gbà mí láàyè kí n bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀.”

40. Nígbà tí ó gbà fún un, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó gbọ́wọ́ sókè kí àwọn eniyan lè dákẹ́. Nígbà tí wọ́n dákẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Heberu.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 21