Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 11:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí.

2. Igbagbọ ni àwọn àgbà àtijọ́ ní, tí wọ́n fi ní ẹ̀rí rere.

3. Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí.

4. Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀.

5. Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.”

6. Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè.

7. Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo.

8. Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ.

9. Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà.

10. Nítorí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀, tí ó jẹ́ pé Ọlọrun ni ó ṣe ètò rẹ̀ tí ó sì kọ́ ọ.

11. Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé.

12. Nítorí èyí, láti ọ̀dọ̀ ẹyọ ọkunrin kan, tí ó ti dàgbà títí, tí ó ti kú sára, ni ọpọlọpọ ọmọ ti jáde, wọ́n pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi iyanrìn etí òkun.

13. Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé.

Ka pipe ipin Heberu 11