6. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí ẹ fẹ́ gba ìyìn eniyan. Ṣugbọn bí ẹrú Kristi, ẹ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti ọkàn wá.
7. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín pẹlu inú dídùn, bí ẹni pé fún Oluwa, kì í ṣe fún eniyan.
8. Nítorí ẹ mọ̀ pé ohun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe, olúwarẹ̀ ìbáà jẹ́ ẹrú tabi kí ó jẹ́ òmìnira, yóo rí èrè gbà lọ́dọ̀ Oluwa.
9. Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju.
10. Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín.
11. Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀.
12. Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí.
13. Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró.
14. Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata.
15. Ẹ jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ láti waasu ìyìn rere alaafia jẹ́ bàtà ẹsẹ̀ yín.
16. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta.
17. Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
18. Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.