Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 8:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Samuẹli bá sọ gbogbo ohun tí OLUWA bá a sọ fún àwọn tí wọ́n ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí àwọn.

11. Ó ṣe àlàyé fún wọn pé, “Bí ọba yín yóo ti máa ṣe yín nìyí: Yóo sọ àwọn ọmọkunrin yín di ọmọ ogun, àwọn kan ninu wọn yóo máa wa kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn kan yóo wà ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń fi ẹsẹ̀ rìn, àwọn kan yóo máa gun ẹṣin níwájú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

12. Yóo fi àwọn kan ṣe ọ̀gágun fún ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, àwọn kan yóo máa ṣe ọ̀gágun fún araadọta ọmọ ogun. Àwọn kan yóo máa ro oko rẹ̀, àwọn kan yóo sì máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀. Àwọn kan yóo máa rọ ohun ìjà fún un, ati àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

13. Àwọn ọmọbinrin yín ni yóo máa ṣe turari fún un, wọn óo sì máa se oúnjẹ fún un.

14. Yóo gba ilẹ̀ oko yín tí ó dára jùlọ ati ọgbà àjàrà ati ti olifi yín, yóo sì fi fún àwọn iranṣẹ rẹ̀.

15. Yóo gba ìdámẹ́wàá ọkà yín ati ti ọgbà àjàrà yín fún àwọn ẹmẹ̀wà ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.

16. Yóo gba àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, ati àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí wọ́n dára jùlọ, yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́.

17. Yóo gba ìdámẹ́wàá agbo aguntan yín, ẹ̀yin gan-an yóo sì di ẹrú rẹ̀.

18. Nígbà tí ó bá yá, ẹ̀yin gan-an ni ẹ óo tún máa pariwo ọba yín tí ẹ yàn fún ara yín, ṣugbọn OLUWA kò ní da yín lóhùn.”

19. Ṣugbọn àwọn eniyan náà kọ̀, wọn kò gba ohun tí Samuẹli wí gbọ́. Wọ́n ní, “Rárá o! A ṣá fẹ́ ní ọba ni.

20. Kí àwa náà lè dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ọba wa lè máa ṣe àkóso wa, kí ó máa ṣiwaju wa lójú ogun, kí ó sì máa jà fún wa.”

21. Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n wí, ó lọ sọ fún OLUWA.

22. OLUWA sọ fún Samuẹli pé, “Ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, kí o sì yan ọba fún wọn.” Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 8