Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 7:3-13 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”

4. Àwọn ọmọ Israẹli bá kó gbogbo oriṣa Baali ati ti Aṣitarotu wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA nìkan.

5. Samuẹli ní kí wọ́n kó gbogbo eniyan Israẹli jọ sí Misipa, ó ní òun óo gbadura sí OLUWA fún wọn níbẹ̀.

6. Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa.

7. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli péjọ sí Misipa, àwọn ọba Filistini kó àwọn eniyan wọn jọ láti gbógun tì wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n.

8. Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Má dákẹ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”

9. Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.

10. Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà.

11. Àwọn ọmọ Israẹli bá kó ogun jáde láti Misipa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ ogun Filistini lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìsàlẹ̀ Betikari, wọ́n ń pa wọ́n bí wọ́n ti ń lé wọn lọ.

12. Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri, ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.”

13. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 7