Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 4:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”

4. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà.

5. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì.

6. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ híhó tí wọn ń hó, wọ́n ní, “Irú ariwo ńlá wo ni àwọn Heberu ń pa ní ibùdó wọn yìí?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àpótí ẹ̀rí OLUWA ni ó dé sí ibùdó àwọn Heberu,

7. ẹ̀rù ba àwọn ará Filistia. Wọ́n ní, “Oriṣa kan ti dé sí ibùdó wọn! A gbé! Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí.

8. A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀.

9. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.”

10. Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn.

11. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli mejeeji.

12. Ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ti ojú ogun sáré pada lọ sí Ṣilo, ó sì dé ibẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sórí láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

13. Ọkàn Eli dàrú gidigidi nítorí àpótí ẹ̀rí náà, ó sì jókòó lórí àga rẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń wo òréré. Ọkunrin tí ó ti ojú ogun wá bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn fún àwọn ará ìlú, ẹ̀rù ba olukuluku, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké.

14. Nígbà tí Eli gbọ́ igbe wọn, ó bèèrè pé, “Kí ni wọ́n ń kígbe báyìí fún?” Ọkunrin náà bá yára wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Eli.

15. Eli ti di ẹni ọdún mejidinlọgọrun-un ní àkókò yìí, ojú rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ má ríran mọ́ rárá.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 4