Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 28:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó ṣe, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Akiṣi sọ fún Dafidi pé, “Ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo jà fún mi.”

2. Dafidi dáhùn pé, “Ó dára, o óo sì rí ohun tí èmi iranṣẹ rẹ lè ṣe.”Akiṣi bá ní, òun óo fi Dafidi ṣe olùṣọ́ òun títí lae.

3. Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli.

4. Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa.

5. Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ.

6. Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.

7. Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.”Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.”

8. Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 28