Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 26:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?”Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi.

18. Kí ló dé tí o fi ń lépa èmi iranṣẹ rẹ? Kí ni mo ṣe? Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi?

19. Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa.

20. Má jẹ́ kí n kú sílẹ̀ àjèjì níbi tí OLUWA kò sí. Kí ló dé tí ọba Israẹli fi ń lépa èmi kékeré yìí, bí ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè?”

21. Saulu dáhùn pé, “Mo ti ṣe ibi, máa bọ̀ Dafidi, ọmọ mi. N kò ní ṣe ọ́ ní ibi mọ́, nítorí pé ẹ̀mí mi níye lórí lójú rẹ lónìí. Mo ti hùwà òmùgọ̀, ohun tí mo ṣe burú pupọ.”

22. Dafidi dáhùn pé, “Ọ̀kọ̀ rẹ nìyí, oluwa mi, jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ wá gbà á.

23. OLUWA a máa san ẹ̀san rere fún àwọn tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ ati olódodo. Lónìí, OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe ọ́ ní ibi, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́.

24. Gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ẹ̀mí rẹ sí lónìí, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì yọ mí kúrò ninu gbogbo ìṣòro.”

25. Saulu dáhùn pé, “Ọlọ́run yóo bukun ọ, ọmọ mi, o óo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.”Dafidi bá bá tirẹ̀ lọ, Saulu sì pada sí ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 26