Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 25:23-34 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Nígbà tí Abigaili rí Dafidi, ó sọ̀kalẹ̀ kíákíá, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ lẹ́bàá

24. ẹsẹ̀ Dafidi, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, gbọ́ ti èmi iranṣẹbinrin rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ru ẹ̀bi àṣìṣe Nabali.

25. Jọ̀wọ́ má ṣe ka aláìmòye yìí sí, nítorí Nabali ni orúkọ rẹ̀, bí orúkọ rẹ̀ tí ń jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwà rẹ̀ rí. Oluwa mi, n kò rí àwọn iranṣẹ rẹ nígbà tí wọ́n wá.

26. OLUWA tìkararẹ̀ ni ó ti ká ọ lọ́wọ́ kò láti má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ati láti má gbẹ̀san. Nisinsinyii, oluwa mi, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ati àwọn tí wọn ń ro ibi sí ọ yóo dàbí Nabali.

27. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí èmi iranṣẹbinrin rẹ mú wá fún ọ kí o sì fi fún àwọn ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé ọ.

28. Jọ̀wọ́ dáríjì mí fún gbogbo àìṣedéédé mi. Dájúdájú OLUWA yóo jẹ́ kí o jọba ati àwọn ọmọ rẹ pẹlu. Nítorí pé ogun OLUWA ni ò ń jà, o kò sì hùwà ibi kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

29. Bí ẹnikẹ́ni bá sì ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní ibi tabi láti pa ọ́, OLUWA yóo dáàbò bò ọ́ bí eniyan ti ń dáàbò bo ohun ìní olówó iyebíye. Ṣugbọn àwọn ọ̀tá rẹ ni a óo parun.

30. Nígbà tí OLUWA bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tí ó sì fi ọ́ jọba ní Israẹli,

31. o kò ní ní ìbànújẹ́ ọkàn pé o ti paniyan rí láìnídìí tabi pé o ti gbẹ̀san ara rẹ. Nígbà tí OLUWA bá sì bukun ọ, jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé èmi iranṣẹbinrin rẹ.”

32. Dafidi dáhùn pé, “Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó rán ọ sí mi lónìí.

33. Ibukun ni fún ọ, fún ọgbọ́n tí o lò ati ohun tí o ṣe lónìí, tí o fà mí sẹ́yìn kúrò ninu ìpànìyàn ati ìgbẹ̀san.

34. OLUWA ti dá mi dúró láti má ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí mi, bí o kò bá yára láti pàdé mi ni, gbogbo àwọn ọkunrin ilé Nabali ni ìbá kú kí ilẹ̀ ọ̀la tó mọ́.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 25