Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 25:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àwọn ọdọmọkunrin náà bá pada lọ sọ gbogbo ohun tí Nabali sọ fún wọn fún Dafidi.

13. Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn.

14. Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Nabali sọ fún Abigaili, iyawo Nabali pé, “Dafidi rán àwọn iranṣẹ láti aṣálẹ̀ wá sọ́dọ̀ oluwa wa, ṣugbọn ó kanra mọ́ wọn.

15. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọkunrin náà tọ́jú wa, wọn kò sì ṣe ibi kankan sí wa, nǹkankan tí ó jẹ́ tiwa kò sì sọnù nígbà tí a wà pẹlu wọn ní oko.

16. Wọ́n dáàbò bò wá tọ̀sán tòru, ní gbogbo ìgbà tí a wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú agbo ẹran wa.

17. Jọ̀wọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáradára, kí o sì pinnu ohun tí o bá fẹ́ ṣe; nítorí pé wọ́n ti gbèrò ibi sí oluwa wa ati ìdílé rẹ̀, ọlọ́kàn líle sì ni oluwa wa, ẹnikẹ́ni kò lè bá a sọ̀rọ̀.”

18. Abigaili bá yára mú igba (200) burẹdi ati ìgò ọtí waini meji ati aguntan marun-un tí wọ́n ti sè ati òṣùnwọ̀n ọkà yíyan marun-un ati ọgọrun-un ìdì àjàrà gbígbẹ ati igba (200) àkàrà tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ dín, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

19. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa lọ ṣiwaju, èmi náà ń bọ̀ lẹ́yìn,” ṣugbọn kò sọ fún ọkọ rẹ̀.

20. Bí ó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, tí ó dé abẹ́ òkè kan, ó rí i tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń bọ̀ níwájú.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 25