Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 23:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí Abiatari, ọmọ Ahimeleki sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó mú aṣọ efodu kan lọ́wọ́.

7. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Keila, ó sọ pé, “Ọlọ́run ti fi Dafidi lé mi lọ́wọ́, nítorí ó ti ti ara rẹ̀ mọ́ inú ìlú olódi tí ó ní ìlẹ̀kùn, tí ó sì lágbára.”

8. Saulu bá pe gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti gbógun ti Keila kí wọ́n sì ká Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ìlú náà.

9. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun.

10. Dafidi ní, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, èmi iranṣẹ rẹ gbọ́ pé Saulu ti pinnu láti wá gbógun ti Keila ati láti pa á run nítorí mi.

11. Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé Saulu lọ́wọ́? Ṣe Saulu yóo wá gẹ́gẹ́ bí mo ti gbọ́? Jọ̀wọ́, OLUWA Ọlọrun Israẹli, fún mi ní èsì.”OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu yóo wá.”

12. Dafidi tún bèèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé e lọ́wọ́?”OLUWA dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóo fà ọ́ lé e lọ́wọ́.”

13. Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́.

14. Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́.

15. Ẹ̀rù ba Dafidi nítorí pé Saulu ń wá ọ̀nà láti pa á.Dafidi ń gbé aṣálẹ̀ Sifi ni Horeṣi.

16. Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú.

17. Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 23