Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí náà ṣe èmi iranṣẹ rẹ ní oore kan, nítorí o ti mú mi dá majẹmu mímọ́ pẹlu rẹ. Ṣugbọn bí o bá rí ohun tí ó burú ninu ìwà mi, ìwọ gan-an ni kí o pa mí; má wulẹ̀ fà mí lé baba rẹ lọ́wọ́ láti pa.”

9. Jonatani bá dáhùn wí pé, “Má ṣe ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ṣé mo lè mọ̀ dájú pé baba mi fẹ́ pa ọ́, kí n má sọ fún ọ?”

10. Dafidi bá bèèrè pé, “Báwo ni n óo ṣe mọ̀ bí baba rẹ bá bínú?”

11. Jonatani dáhùn pé, “Máa bọ̀, jẹ́ kí á lọ sinu pápá.” Àwọn mejeeji sì lọ.

12. Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣe ẹlẹ́rìí láàrin èmi pẹlu rẹ. Ní àkókò yìí lọ́la tabi ní ọ̀tunla n óo wádìí nípa rẹ̀ lọ́wọ́ baba mi. Bí inú rẹ̀ bá yọ́ sí ọ n óo ranṣẹ sí ọ.

13. Ṣugbọn bí ó bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ níbi, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí OLUWA pa mí bí n kò bá sọ fún ọ, kí n sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sá àsálà. Kí OLUWA wà pẹlu rẹ bí ó ti ṣe wà pẹlu baba mi.

14. Bí mo bá sì wà láàyè kí o fi ìfẹ́ òtítọ́ OLUWA hàn sí mi kí n má baà kú. Ṣugbọn bí mo bá kú,

15. má jẹ́ kí àánú rẹ kúrò ninu ilé mi títí lae. Nígbà tí OLUWA bá ti ké gbogbo àwọn ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀ ayé,

16. má jẹ́ kí orúkọ Jonatani di ìkékúrò ní ilé Dafidi. Kí OLUWA gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá Dafidi.”

17. Jonatani tún mú kí Dafidi ṣe ìbúra lẹ́ẹ̀kan sí i, pẹlu ìfẹ́ tí ó ní sí i. Nítorí pé, Jonatani fẹ́ràn rẹ̀ bí ó ti fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀.

18. Lẹ́yìn náà, Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, àwọn eniyan yóo sì mọ̀ bí o kò bá wá síbi oúnjẹ nítorí ààyè rẹ yóo ṣófo.

19. Bí wọn kò bá rí ọ ní ọjọ́ keji, wọn yóo mọ̀ dájú pé o kò sí láàrin wọn. Nítorí náà, lọ sí ibi tí o farapamọ́ sí ní ìjelòó, kí o sì farapamọ́ sẹ́yìn àwọn òkúta ọ̀hún nnì.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20