Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:20-33 BIBELI MIMỌ (BM)

20. N óo sì ta ọfà mẹta sí ìhà ibẹ̀ bí ẹni pé mo ta wọ́n sí àmì kan.

21. N óo rán ọmọkunrin kan láti wá àwọn ọfà náà. Bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wò ó àwọn ọfà náà wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,’ kí o jáde wá, nítorí bí OLUWA tí ń bẹ, kò sí ewu kankan fún ọ.

22. Ṣugbọn bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wo àwọn ọfà náà níwájú rẹ,’ máa bá tìrẹ lọ nítorí OLUWA ni ó fẹ́ kí o lọ.

23. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi pẹlu rẹ jọ sọ, ranti pé OLUWA wà láàrin wa laelae.”

24. Dafidi farapamọ́ ninu pápá, ní ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, Saulu ọba jókòó láti jẹun.

25. Ọba jókòó níbi tí ó máa ń jókòó sí ní ẹ̀gbẹ́ ògiri, Jonatani jókòó ní iwájú rẹ̀. Abineri sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Saulu. Ṣugbọn ààyè Dafidi ṣófo.

26. Sibẹ Saulu kò sọ nǹkankan nítorí pé ó rò pé bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi, tí ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ ni.

27. Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?”

28. Jonatani dáhùn pé, “Ó gbààyè lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu.

29. Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.”

30. Inú bí Saulu gidigidi sí Jonatani, ó ní, “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ati aláìgbọràn obinrin yìí, mo mọ̀ wí pé ò ń gbè lẹ́yìn Dafidi, o sì ń ta àbùkù ara rẹ ati ìhòòhò ìyá rẹ.

31. Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.”

32. Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?”

33. Saulu bá ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn, ó fẹ́ pa á. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ dájú pé, baba òun pinnu láti pa Dafidi.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20