Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 19:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Saulu tún rán àwọn iranṣẹ náà lọ wo Dafidi, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé e wá fún mi ti òun ti ibùsùn rẹ̀, kí n pa á.”

16. Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà dé, wọ́n bá ère ní orí ibùsùn pẹlu ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ ní ìgbèrí rẹ̀.

17. Saulu sì bèèrè lọ́wọ́ Mikali pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí, tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sá àsálà?”Mikali dá Saulu lóhùn pé, “Ó sọ wí pé òun yóo pa mí bí n kò bá jẹ́ kí òun sá lọ.”

18. Dafidi sá àsálà, ó sá lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama, ó sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe sí i fún un. Òun pẹlu Samuẹli sì lọ ń gbé Naioti.

19. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Naioti ní Rama,

20. ó rán àwọn iranṣẹ láti mú un. Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà rí ẹgbẹ́ àwọn wolii tí wọn ń jó, tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, pẹlu Samuẹli ní ààrin wọn gẹ́gẹ́ bí olórí wọn, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé àwọn iranṣẹ náà, àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀.

21. Nígbà tí Saulu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, ó rán àwọn mìíràn, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ó rán àwọn oníṣẹ́ ní ìgbà kẹta, àwọn náà tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

22. Òun pàápàá dìde ó lọ sí Rama. Nígbà tí ó dé etí kànga jíjìn tí ó wà ní Seku, ó bèèrè ibi tí Samuẹli ati Dafidi wà. Wọ́n sì sọ fún un wí pé, wọ́n wà ní Naioti ti Rama.

23. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sí Naioti ti Rama, bí ó ti ń lọ, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 19