Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 18:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Saulu gba Dafidi sọ́dọ̀ ní ọjọ́ náà, kò sì jẹ́ kí ó pada sílé baba rẹ̀.

3. Jonatani bá bá Dafidi dá majẹmu, nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.

4. Ó bọ́ aṣọ tí ó wọ̀ fún Dafidi, ó sì kó ihamọra rẹ̀ pẹlu idà ati ọfà ati àmùrè rẹ̀ fún un.

5. Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn.

6. Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin.

7. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé,“Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.”

8. Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.”

9. Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi.

10. Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu.

11. Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji.

12. Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀.

13. Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

14. Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 18