Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 18:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

14. Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀.

15. Saulu tún bẹ̀rù Dafidi sí i nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀.

16. Ṣugbọn gbogbo àwọn ará Israẹli ati Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó jẹ́ olórí tí ń ṣe àṣeyọrí.

17. Saulu sọ fún Dafidi pé, “Merabu ọmọbinrin mi àgbà nìyí, n óo fún ọ kí o fi ṣe aya, ṣugbọn o óo jẹ́ ọmọ ogun mi, o óo sì máa ja ogun OLUWA.” Nítorí Saulu rò ninu ara rẹ̀ pé, àwọn Filistini ni yóo pa Dafidi, òun kò ní fi ọwọ́ ara òun pa á.

18. Dafidi dáhùn pé, “Ta ni èmi ati ìdílé baba mi tí n óo fi di àna ọba?”

19. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó yẹ kí Saulu fi Merabu fún Dafidi, Adirieli ará Mehola ni ó fún.

20. Ṣugbọn Mikali ọmọbinrin Saulu nífẹ̀ẹ́ Dafidi; nígbà tí Saulu gbọ́, inú rẹ̀ dùn sí i.

21. Ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo fi Mikali fún Dafidi kí ó lè jẹ́ ìdẹkùn fún un, àwọn Filistini yóo sì rí i pa.” Saulu ṣèlérí fún Dafidi lẹẹkeji pé, “O óo di àna mi.”

22. Saulu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ lọ bá Dafidi sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ pé, inú ọba dùn sí i lọpọlọpọ, ati pé gbogbo àwọn iranṣẹ ọba fẹ́ràn rẹ̀, nítorí náà ó yẹ kí ó fẹ́ ọmọ ọba.”

23. Nígbà tí wọ́n sọ èyí fún Dafidi, ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe nǹkan kékeré ni láti jẹ́ àna ọba, talaka ni mí, èmi kì í sì í ṣe eniyan pataki.”

24. Àwọn iranṣẹ náà sọ èsì tí Dafidi fún wọn fún Saulu.

25. Saulu sì rán wọn pé kí wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Ọba kò bèèrè ẹ̀bùn igbeyawo kankan lọ́wọ́ rẹ ju ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá ọba.” Saulu rò pé àwọn ará Filistia yóo tipa bẹ́ẹ̀ pa Dafidi.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 18