Saulu sọ fún Dafidi pé, “Merabu ọmọbinrin mi àgbà nìyí, n óo fún ọ kí o fi ṣe aya, ṣugbọn o óo jẹ́ ọmọ ogun mi, o óo sì máa ja ogun OLUWA.” Nítorí Saulu rò ninu ara rẹ̀ pé, àwọn Filistini ni yóo pa Dafidi, òun kò ní fi ọwọ́ ara òun pa á.