Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 16:13-23 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama.

14. Ẹ̀mí OLUWA kúrò lára Saulu, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA sì ń dà á láàmú.

15. Àwọn iranṣẹ Saulu wí fún un pé, “Wò ó! Ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń dà ọ́ láàmú;

16. fún àwa iranṣẹ rẹ tí a wà níwájú rẹ láṣẹ láti wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára. Ìgbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bá bà lé ọ, yóo máa fi hapu kọrin, ara rẹ yóo sì balẹ̀.”

17. Saulu bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára, kí wọ́n sì mú un wá siwaju òun.

18. Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.”

19. Saulu bá ranṣẹ sí Jese pé kí ó fi Dafidi, ọmọ rẹ̀ tí ń tọ́jú agbo ẹran ranṣẹ sí òun.

20. Jese di ẹrù burẹdi ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ati waini tí wọ́n rọ sinu ìgò aláwọ pẹlu ọmọ ewúrẹ́ kan, ó kó wọn rán Dafidi sí Saulu.

21. Dafidi wá sọ́dọ̀ Saulu, ó sì ń bá a ṣiṣẹ́. Saulu fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, ó sì di ẹni tí ń ru ihamọra Saulu.

22. Saulu ranṣẹ sí Jese, ó ní, “Jẹ́ kí Dafidi máa bá mi ṣiṣẹ́ nítorí ó ti bá ojurere mi pàdé.”

23. Nígbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú bá ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá sórí Saulu, Dafidi a máa ta hapu fún un, ara Saulu á balẹ̀, ẹ̀mí burúkú náà a sì fi í sílẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 16