Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 15:14-24 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ni igbe àwọn aguntan ati ti àwọn mààlúù tí mò ń gbọ́ yìí?”

15. Saulu dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan mi ni wọ́n kó wọn lọ́dọ̀ àwọn ará Amaleki. Wọ́n ṣa àwọn aguntan ati àwọn mààlúù tí wọ́n dára jùlọ pamọ́ láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ. A sì ti pa gbogbo àwọn yòókù run patapata.”

16. Samuẹli bá sọ fún un pé, “Dákẹ́! Jẹ́ kí n sọ ohun tí OLUWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”Saulu dáhùn pé, “Mò ń gbọ́.”

17. Samuẹli ní, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò jámọ́ nǹkankan lójú ara rẹ, sibẹsibẹ ìwọ ni olórí gbogbo ẹ̀yà Israẹli. Ìwọ ni OLUWA fi òróró yàn ní ọba wọn.

18. Ó sì rán ọ jáde pẹlu àṣẹ pé kí o pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ará Amaleki run. Ó ní kí o gbógun tì wọ́n títí o óo fi pa wọ́n run patapata.

19. Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ OLUWA mọ? Kí ló dé tí o fi kó ìkógun, tí o sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA?”

20. Saulu dá a lóhùn pé, “Mo ti pa òfin OLUWA mọ́, mo jáde lọ bí o ti wí fún mi pé kí n jáde lọ, mo mú Agagi ọba pada bọ̀, mo sì pa gbogbo àwọn ará Amaleki run.

21. Ṣugbọn àwọn eniyan mi ni wọ́n kó ìkógun aguntan ati àwọn mààlúù tí ó dára jùlọ lára àwọn ohun tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti fi wọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ ní Giligali.”

22. Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ.

23. Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.”

24. Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 15