Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 13:4-10 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Gbogbo Israẹli gbọ́ pé Saulu ti ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini ati pé àwọn ọmọ Israẹli ti di ohun ìríra lójú àwọn ará Filistia. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá jáde láti wá darapọ̀ mọ́ Saulu ní Giligali.

5. Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ.

6. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé ilẹ̀ ti ká àwọn mọ́, nítorí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini dùn wọ́n, wọ́n bá ń farapamọ́ káàkiri; àwọn kan sá sinu ihò ilẹ̀, àwọn mìíràn sì sá sinu àpáta, inú ibojì ati inú kànga.

7. Àwọn mìíràn ninu wọn ré odò Jọdani kọjá sí agbègbè Gadi ati Gileadi.Gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu Saulu sì wà ninu ìbẹ̀rù ńlá.

8. Ọjọ́ meje ni ó fi dúró de Samuẹli, bí Samuẹli ti wí. Ṣugbọn Samuẹli kò wá sí Giligali. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn Saulu.

9. Nítorí náà, Saulu ní kí wọ́n gbé ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia wá fún òun, ó sì rú ẹbọ.

10. Bí ó ti parí rírú ẹbọ sísun náà tán ni Samuẹli dé. Saulu lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 13