Jonatani ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini tí wọ́n wà ní Geba; gbogbo àwọn ará Filistia sì gbọ́ nípa rẹ̀. Saulu bá fọn fèrè ogun jákèjádò ilẹ̀ náà, wí pé “Ẹ jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́ èyí.”