Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 13:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”

15. Samuẹli kúrò ní Giligali, ó lọ sí Gibea ní Bẹnjamini. Saulu ka àwọn eniyan tí wọ́n kù lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600).

16. Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, pẹlu àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pàgọ́ sí Geba ní agbègbè Bẹnjamini. Àgọ́ ti àwọn ará Filistia wà ní Mikimaṣi.

17. Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà, mẹta ninu ọmọ ogun Filistini jáde láti inú àgọ́ wọn, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Ofira ní agbègbè Ṣuali,

18. àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀.

19. Kò sí ẹyọ alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí pé àwọn ará Filistia ti pinnu pé, àwọn kò ní gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti rọ idà ati ọ̀kọ̀ fúnra wọn.

20. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ pọ́n ohun ìtúlẹ̀ wọn ati ọkọ́ ati àáké ati dòjé, wọ́n níláti lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia.

21. Owó díẹ̀ ni àwọn Filistia máa ń gbà, láti bá wọn pọ́n ohun ìtúlẹ̀ ati ọkọ́, wọ́n ń gba ìdámẹ́ta owó ṣekeli láti pọ́n àáké ati láti tún irin tí ó wà lára ohun ìtúlẹ̀ ṣe.

22. Nítorí náà, ní ọjọ́ ogun yìí kò sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ó ní idà tabi ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, àfi Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀.

23. Ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan sì lọ sí ọ̀nà Mikimaṣi.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 13