Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 10:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí:

2. Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’

3. Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́.

4. Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.

5. Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

6. Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀.

7. Nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣe ohunkohun tí ó bá wá sọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 10